1 Chronicles 10:12 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
gbogbo àwọn akọni ọkunrin tí wọ́n gbóyà gidigidi gbéra, wọ́n lọ gbé òkú Saulu ati òkú àwọn ọmọ rẹ̀ wá sí Jabeṣi, wọ́n sì sin egungun wọn sí abẹ́ igi oaku ní Jabeṣi, wọ́n sì gbààwẹ̀ fún ọjọ́ meje.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn dide, gbogbo awọn ọkunrin ogun, nwọn si gbé okú Saulu lọ, ati okú awọn ọmọ rẹ̀, nwọn wá si Jabeṣi, nwọn si sìn egungun wọn labẹ igi oaku ni Jabeṣi, nwọn si gbawẹ ni ijọ meje.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Gbogbo àwọn akọni ọkùnrin wọn lọ láti mú àwọn ará Ṣọ́ọ̀lù àti àwọn ọmọ Rẹ̀, wọ́n sì kó wọn wá sí Jábésì. Nígbà náà, wọ́n sin egungun wọn sábẹ́ igi ńlá ní Jábésì, wọ́n sì gbààwẹ̀ fún ọjọ́ méje.