1 Chronicles 10:13 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Bẹ́ẹ̀ ni Saulu ṣe kú nítorí aiṣododo rẹ̀; ó ṣàìgbọràn sí àṣẹ OLUWA, ó sì lọ ṣe àyẹ̀wò lọ́dọ̀ abókùúsọ̀rọ̀, ó lọ bèèrè ìtọ́sọ́nà níbẹ̀,
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bẹ̃ni Saulu kú ninu ẹ̀ṣẹ rẹ̀ ti o da si Oluwa, nitori ọ̀rọ Oluwa, ti on kò kiyesi, ati pẹlu nitori o lọ bère ọ̀ràn lọwọ abokusọrọ, lati ṣe ibere.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣọ́ọ̀lù kú nítorí kò se òtítọ́ sí OLÚWA: Kò pa ọ̀rọ̀ OLÚWA mọ́ pẹ̀lú, ó tọ abókúsọ̀rọ̀ lọ fún ìtọ́sọ́nà.