1 Chronicles 10:4 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Saulu ba sọ fún ọdọmọkunrin tí ń ru ihamọra rẹ̀ pé, “Fa idà rẹ yọ, kí o sì gún mi pa, kí àwọn aláìkọlà ará Filistia má baà fi mi ṣẹ̀sín.” Ṣugbọn ẹni tí ń ru ihamọra rẹ̀ kọ̀, nítorí pe ẹ̀rù bà á; nítorí náà, Saulu fa idà ara rẹ̀ yọ, ó sì ṣubú lé e.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbana ni Saulu wi fun ẹniti o ru ihamọra rẹ̀ pe, Fa idà rẹ yọ, ki o si fi gun mi, ki awọn alaikọla wọnyi ki o má ba wá fi mi ṣẹsin. Ṣugbọn ẹniti o ru ihamọra rẹ̀ kọ̀, nitori ẹ̀ru ba a gidigidi. Bẹ̃ni Saulu si mu idà, o si ṣubu le e.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣọ́ọ̀lù sì sọ fún ẹni tí ó gbé ìhámọ́ra Rẹ̀ pé, Fa idà rẹ yọ, kí o sì fi gún mi, kí àwọn aláìkọlà wọ̀nyí má wá láti bú mi. Ṣùgbọ́n ẹni tí ó ń gbé ìhámọ́ra Rẹ̀ ń bẹ̀rù, kò sì le ṣe é; Bẹ́ẹ̀ ni Ṣọ́ọ̀lù mú idà tirẹ̀ ó sì subú lé e.