1 Chronicles 11:10 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Àwọn tí wọ́n jẹ́ olórí ninu àwọn akọni ọmọ ogun Dafidi nìwọ̀nyí; àwọn ni wọ́n fọwọsowọpọ pẹlu àwọn ọmọ Israẹli, láti fi Dafidi jọba, tí wọ́n sì fi ìdí ìjọba rẹ̀ múlẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ìlérí tí OLUWA ti ṣe fún Israẹli.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Wọnyi si ni olori awọn ọkunrin akọni ti Dafidi ni; awọn ti o fi ara wọn mọ ọ girigiri ni ijọba rẹ̀, pẹlu gbogbo Israeli, lati fi i jọba, gẹgẹ bi ọ̀rọ Oluwa fun Israeli.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn wọ̀nyí sì ni ìjòyè alágbára ọkùnrin Dáfídì, àwọn pẹ̀lú gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, wọ́n sì fún ìjọba Rẹ̀ ní àtìlẹ́yìn tó lágbára láti mú un tàn káàkiri gbogbo ilẹ̀, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti sèlérí: