1 Chronicles 11:18 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Àwọn akọni mẹta náà bá la àgọ́ àwọn ọmọ ogun Filistia já, dé ibi kànga náà, wọ́n sì bu omi náà wá fún Dafidi. Ṣugbọn ó kọ̀, kò mu ún; kàkà bẹ́ẹ̀, ó tú u sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹbọ fún OLUWA.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn mẹta na si la inu ogun awọn ara Filistia kọja, nwọn si fa omi jade lati inu kanga Betlehemu, lati ẹnu-bodè, nwọn gbé e, nwọn si mu u tọ̀ Dafidi wá: Dafidi kò si fẹ mu u, ṣugbọn o tu u silẹ fun Oluwa,
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bẹ́ẹ̀ ni àwọn mẹ́ta náà sì là láti ogun ará Fílístínì, ó sì fa omi jáde láti inú kànga ní ẹ̀gbẹ́ ẹnu bodè Bẹ́tílẹ́hẹ́mù ó sì gbé padà tọ Dáfídì wá. Ṣùgbọ́n ó kọ̀ láti mu ú: dípò, ó sì tú jáde níwájú OLÚWA.