1 Chronicles 11:19 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ó ní, “Kí á má rí i pé mo ṣe nǹkan yìí níwájú Ọlọrun mi. Ǹjẹ́ ó yẹ kí n mu ẹ̀jẹ̀ àwọn ọkunrin wọnyi?” Nítorí pé ẹ̀mí wọn ni wọ́n fi wéwu kí wọn tó rí omi yìí bù wá; nítorí náà ni ó ṣe kọ̀, tí kò sì mu ún. Ó jẹ́ ohun ìgboyà tí àwọn akọni mẹta náà ṣe.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si wipe, Ki Ọlọrun mi má jẹ ki emi ki o ṣe eyi: ki emi ki o ha mu ẹ̀jẹ awọn ọkunrin wọnyi, ti nwọn fi ẹmi wọn wewu? nipa ẹmi wọn ni nwọn fi mu u wá. Nitorina ni on kò ṣe fẹ mu u, nkan wọnyi li awọn akọni mẹta wọnyi ṣe.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Kí Ọlọ́run dẹ́kun kí èmi ó má ṣe se èyí!” ó wí pé. “Se kí èmi kí ó mú ẹ̀jẹ̀ ọkùnrin yí ẹnití ó fi ẹ̀mí Rẹ̀ wéwu?” Nítorí wọ́n fi ẹ̀mí wọn wéwu láti mú padà wá, Dáfídì kò ní mu ú. Nǹkan wọ̀nyí ni àwọn akọni mẹ́ta ọkùnrin náà ṣe ohun ìyanu ńlá.

Recommended Reading