1 Chronicles 11:20 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Abiṣai, arakunrin Joabu, ni olórí àwọn ọgbọ̀n ọ̀gágun. Ó fi ọ̀kọ̀ rẹ̀ pa ọọdunrun eniyan, nípa bẹ́ẹ̀ òkìkí tirẹ̀ náà súnmọ́ ti àwọn akọni mẹta náà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati Abiṣai arakunrin Joabu, on li olori ninu awọn mẹta: nitoriti o gbé ọ̀kọ rẹ̀ soke si ọ̃dunrun o pa wọn, o si ni orukọ ninu awọn mẹta.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ábíṣáì arákùnrin Jóábù ìjòyè àwọn mẹ́ta. Ó sì gbé ọ̀kọ̀ Rẹ̀ sókè lórí àwọn ọ̀dúnrún àwọn ènìyàn, àwọn ẹni tí ó pa, bẹ́ẹ̀ ni ó sì di olókìkí gẹ́gẹ́ bí àwọn mẹ́ta.