1 Chronicles 11:22 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Bẹnaya, ọmọ Jehoiada, láti ìlú Kabiseeli, jẹ́ ọmọ ogun tí ó ti ṣe ọpọlọpọ ohun ìyanu, ó pa àwọn abàmì eniyan meji ará Moabu. Ó wọ ihò lọ pa kinniun kan ní ọjọ́ kan tí yìnyín bo ilẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Benaiah, ọmọ Jehoiada, ọmọ akọni ọkunrin kan ti Kabseeli, ẹniti o pọ̀ ni iṣe agbara, o pa awọn ọmọ Arieli meji ti Moabu; on sọkalẹ, o si pa kiniun kan ninu iho lakoko sno.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bẹ́náyà ọmọ Jéhóíádà ó sì jẹ́ akọni oníjà láti Kábísélì, ẹni tí ó se iṣẹ́ agbára ńlá. Ó sì pa méjì nínú àwọn ọkùnrin tí ó dára jù, ó sì tún sọ̀kalẹ̀ lọ sí inú ihò lákókò sno ó sì pa kìnnìún kan