1 Chronicles 11:23 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ó pa ará Ijipti kan tí ó ga ju mita meji lọ. Ará Ijipti náà gbé ọ̀kọ̀ tí ó tóbi lọ́wọ́. Ṣugbọn kùmọ̀ ni Bẹnaya mú lọ́wọ́ lọ bá a, ó gba ọ̀kọ̀ tí ó wà lọ́wọ́ rẹ̀, ó sì fi pa á.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si pa ara Egipti kan, ọkunrin ti o si sigbọnlẹ igbọnwọ marun ni gigun rẹ̀; ati li ọwọ ara Egipti na ni ọ̀kọ kan wà bi idubu igi awunṣọ; o si sọ̀kalẹ tọ ọ lọ pẹlu ọpa, a si já ọ̀kọ li ọwọ ara Egipti na, o si fi ọ̀kọ rẹ̀ pa a.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó sì pa ara Éjíbítì ẹni tí ó ga ní ìwọ̀n ẹsẹ̀ méje àti ààbọ̀ ṣùgbọ́n àwọn ará Éjíbítì wọn ní ọ̀kọ̀ gẹ́gẹ́ bí ìdubú igi àwunṣọ àti ọ̀pá ní ọwọ́ Rẹ̀, Bénáyà sọ̀kalẹ̀ lórí Rẹ̀ pẹ̀lú kùmọ̀. Ó sì gba ọ̀kọ̀ náà láti ọwọ́ ará Éjíbítì ó sì pa á pẹ̀lú ọ̀kọ̀ Rẹ̀.