1 Chronicles 11:25 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ó di olókìkí láàrin àwọn ọgbọ̀n ọ̀gágun; ṣugbọn òkìkí tirẹ̀ kò tó ti àwọn akọni mẹta náà. Dafidi bá fi ṣe olórí àwọn tí ń ṣọ́ ọba.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Kiyesi i, o li ọla jù awọn ọ̀gbọn lọ, ṣugbọn kò to awọn mẹta iṣaju. Dafidi si fi ṣe olori awọn igbimọ ile rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó sì ní ọlá púpọ̀ ju àwọn ọgbọ̀n (30) lọ, ṣùgbọ́n a kò káà láàrin àwọn mẹ́tẹ̀ta. Dáfídì sì fi sí ìkáwọ́ àwọn ẹ̀sọ́.