1 Chronicles 11:3 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nítorí náà, àwọn àgbààgbà Israẹli wá sọ́dọ̀ Dafidi ọba, ní Heburoni. Dafidi sì bá wọn dá majẹmu níbẹ̀ níwájú OLUWA. Wọ́n fi òróró yàn án ní ọba lórí Israẹli, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ OLUWA láti ẹnu Samuẹli.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitorina ni gbogbo awọn agbagba Israeli ṣe tọ ọba wá ni Hebroni; Dafidi si ba wọn da majẹmu ni Hebroni niwaju Oluwa; nwọn si fi ororo yan Dafidi li ọba lori Israeli, gẹgẹ bi ọ̀rọ Oluwa nipa ọwọ Samueli.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí gbogbo àwọn ìjòyè Ísírẹ́lì tí wọ́n ti wá sọ́dọ̀ ọba Dáfídì ni Hébúrónì. Ó sì ṣe májẹ̀mú pẹ̀lú wọn ní Hébúrónì níwájú OLÚWA, wọ́n sì fi àmìn òróró yan Dáfídì ọba lórí Ísírẹ́lì, gẹ́gẹ́ bí OLÚWA ti ṣèlérí láti ọ̀dọ̀ Ṣámúẹ́lì.