1 Chronicles 12:15 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Àwọn ni wọ́n la odò Jọdani kọjá ninu oṣù kinni, ní àkókò ìgbà tí ó kún bo bèbè rẹ̀, wọ́n sì ṣẹgun gbogbo àwọn tí wọ́n wà ní àfonífojì, ní apá ìhà ìlà oòrùn ati apá ìwọ̀ oòrùn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Wọnyi li awọn ti o gòke odò Jordani li oṣù ekini, nigbati o kún bò gbogbo bèbe rẹ̀; nwọn si le gbogbo awọn ti o wà li afonifoji ninu ila-õrùn, ati niha iwọ-õrùn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn ni ẹni tí ó rékọjá Jọ́dánì ní oṣù àkọ́kọ́ nígbà tí ó kún bo gbogbo bèbè Rẹ̀, wọ́n sì lé gbogbo àwọn tí ó ń gbé nínú àfonífojì, lọ sí ìlà oòrùn àti níhà ìwọ̀ oòrùn.