1 Chronicles 12:17 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Dafidi lọ pàdé wọn, ó ní, “Tí ẹ bá wá láti darapọ̀ mọ́ mi gẹ́gẹ́ bí ọ̀rẹ́, ati láti ràn mí lọ́wọ́, inú mi dùn sí yín; ṣugbọn bí ẹ bá wá ṣe amí fún àwọn ọ̀tá mi, nígbà tí ó ti jẹ́ pé n kò ní ẹ̀bi, Ọlọrun àwọn baba wa rí yín, yóo sì jẹ yín níyà.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Dafidi si jade lọ ipade wọn, o si dahun o si wi fun wọn pe, Bi o ba ṣepe ẹnyin tọ̀ mi wá li alafia lati ràn mi lọwọ, ọkàn mi yio ṣọkan pẹlu nyin: ṣugbọn bi o ba ṣepe ẹnyin wá lati fi mi hàn fun awọn ọta mi, nigbati ẹbi kò si lọwọ mi, ki Ọlọrun awọn baba wa ki o wò o, ki o si ṣe idajọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Dáfídì sì lọ láti lọ pàdé wọn ó sì wí fún wọn pé, “Tí ẹ bá wá sọ́dọ̀ mi lálàáfíà, láti ràn mí lọ́wọ́ mo sẹtan láti mú un yín wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú mi ṣùgbọ́n tí ẹ bá wá láti dá mi sí fún àwọn ọ̀ta mi nígbà tí ọwọ́ mi bá mọ́ kúrò nínú ìwà agbára, kí Ọlọ́run àwọn baba wa kí ó sì ri kí ó sì ṣe ìdájọ́.”