1 Chronicles 12:18 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ẹ̀mí Ọlọrun bá bà lé Amasai, olórí àwọn ọgbọ̀n ọmọ ogun olókìkí, ó bá dáhùn pé, “Tìrẹ ni wá, Dafidi; a sì wà pẹlu rẹ, ọmọ Jese! Alaafia, alaafia ni fún ọ, alaafia sì ni fún àwọn olùrànlọ́wọ́ rẹ! Nítorí pé Ọlọrun rẹ ń ràn ọ́ lọ́wọ́.” Dafidi bá gbà wọ́n, ó sì fi wọ́n ṣe olórí àwọn ọmọ ogun rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbana ni ẹmi bà lé Amasai, ti iṣe olori awọn ọgbọn na, wipe, Tirẹ li awa, Dafidi, tirẹ li a si nṣe, iwọ ọmọ Jesse: alafia! alafia ni fun ọ! alafia si ni fun awọn oluranlọwọ rẹ; nitori Ọlọrun rẹ ni nràn ọ lọwọ. Dafidi si gbà wọn, o si fi wọn jẹ olori ẹgbẹ-ogun.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà Ẹ̀mí Mímọ́ wa sórí Ámásáyà ìjòyè àwọn ọgbọ̀n, ó sì wí pé: “Tìrẹ ni àwa ń se, ìwọ Dáfídì! Àwa pẹ̀lú rẹ, ìwọ ọmọ Jésè! Àlàáfíà, àlàáfíà fún o, àti àlàáfíà fún àwọn tí ó ràn ó lọ́wọ́, nítorí Ọlọ́run Rẹ̀ yóò ràn ọ́ lọ́wọ́.” Bẹ́ẹ̀ ni Dáfídì sì gbà wọ́n ó sì mú wọn jẹ olórí ẹgbẹ́ ogun.