1 Chronicles 12:19 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Àwọn kan ninu ẹ̀yà Manase darapọ̀ mọ́ Dafidi nígbà tí òun pẹlu àwọn ará Filistia wá láti bá Saulu jagun. (Sibẹsibẹ kò lè ran àwọn Filistia lọ́wọ́, nítorí pé lẹ́yìn tí àwọn ọba àwọn Filistini jíròrò láàrin ara wọn, wọ́n ní “Ewu ń bẹ nítorí pé yóo darapọ̀ pẹlu Saulu, ọ̀gá rẹ̀.”) Wọ́n bá dá a pada lọ sí Sikilagi.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ninu ẹyà Manasse si ya si ọdọ Dafidi, nigbati o ba awọn ara Filistia wá lati ba Saulu jagun, ṣugbọn nwọn kò ràn wọn lọwọ: nitori awọn olori awọn ara Filistia, nigbati nwọn gbero, rán a lọ wipe, Ti on ti ori wa ni on o fi pada lọ si ọdọ Saulu oluwa rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Díẹ̀ nínú àwọn ọkùnrin Mánásè sì yà sí ọ̀dọ̀ Dáfídì nígbà tí ó lọ pẹ̀lú àwọn ará Fílístínì láti bá Ṣọ́ọ̀lù jà. (Òun àti àwọn ọkùnrin Rẹ̀ wọn kò sì ran ará Fílístínì lọ́wọ́ nítorí, lẹ́yìn àjùmọ̀sọ̀rọ̀, àwọn olórí wọn rán wọn jáde, wọ́n sì wí pé Yóò ná wa ní orí wa tí ó bá sì fi sílẹ̀ fún ọ̀gá Rẹ̀ Ṣọ́ọ̀lù).