1 Chronicles 12:29 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Láti inú ẹ̀yà Bẹnjamini, tí wọ́n jẹ́ ẹ̀yà kan náà pẹlu Saulu, àwọn tí wọ́n wá jẹ́ ẹẹdẹgbaaji (3,000). Tẹ́lẹ̀ rí, ó fẹ́rẹ̀ jẹ́ pé gbogbo àwọn ẹ̀yà Bẹnjamini ni wọ́n jẹ́ olóòótọ́ sí ìdílé Saulu.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati ninu awọn ọmọ Benjamini, awọn arakunrin Saulu ẹgbẹ̃dogun: nitori titi di isisiyi, ọ̀pọlọpọ ninu wọn li o ti ntọju iṣọ ile Saulu.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn arákùnrin Bẹ́ńjámínì ìbátan ọkùnrin Ṣọ́ọ̀lù ẹgbẹ̀ẹ́dógún (3,000), ọ̀pọ̀ nínú àwọn ẹni tí ó si kù ní olóòtọ́ sí ilé Ṣọ́ọ̀lù títí di ìgbà náà;