1 Chronicles 12:32 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Láti inú ẹ̀yà Isakari, àwọn igba (200) olórí ni wọ́n wá, àwọn tí wọ́n mọ ohun tí ó bá ìgbà mu, ati ohun tí ó yẹ kí Israẹli ṣe; wọ́n wá pẹlu àwọn tí wọ́n wà lábẹ́ wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati ninu awọn ọmọ Issakari, ti o ni oye akoko, lati mọ̀ ohun ti Israeli iba ma ṣe; olori wọn jẹ igba; ati gbogbo awọn arakunrin wọn mbẹ ni ikawọ wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn ọkùnrin Ísákárì, àwọn ẹni tí ó mọ ìgbà yẹn ó sì mọ ohun tí Ísírẹ́lì yóò se ìgbà (200) àwọn ìjòyè, pẹ̀lú gbogbo àwọn ìbátan wọn lábẹ́ òfin wọn.