1 Chronicles 12:33 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Láti inú ẹ̀yà Sebuluni, ọ̀kẹ́ meji ó lé ẹgbaarun (50,000) àwọn ọmọ ogun, tí wọ́n gbóyà, tí wọ́n mọ̀ nípa ogun jíjà, tí wọ́n sì ní gbogbo ihamọra ogun ni wọ́n wá láti ran Dafidi lọ́wọ́ pẹlu ọkàn kan.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ninu ti Sebuluni, iru awọn ti o jade lọ si ogun ti o mọ̀ ogun iwé, pẹlu gbogbo ohun èlo ogun, ẹgbamẹ̃dọgbọn; ti nwọn kì ifi iye-meji tẹgun.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn ọkùnrin Ṣébúlúnì, àti àwọn jagunjagun tí ó ti nípa ogun múra fún ogun pẹ̀lú orísirísi ohun èlò ìjà, láti ran Dáfídì lọ́wọ́ pẹ̀lú àwọn tí kò fi iyèméjì ṣe ìjólóótọ́ wọn jẹ́ ẹgbàámẹ́dọ́gbọ̀n (50,000);