1 Chronicles 12:38 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Gbogbo wọn ni wọ́n ti dira ogun, tí wọ́n wá sí Heburoni pẹlu ìpinnu láti fi Dafidi jọba lórí Israẹli. Àwọn ọmọ Israẹli yòókù náà sì pinnu bákan náà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Gbogbo awọn ọkunrin ogun wọnyi ti nwọn mọ̀ bi a iti itẹ ogun, nwọn fi ọkàn pipe wá si Hebroni, lati fi Dafidi jọba lori Israeli: gbogbo awọn iyokù ninu Israeli si jẹ oninu kan pẹlu lati fi Dafidi jẹ ọba.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Gbogbo èyí ni àwọn ọkùnrin ológun tí ó fi ara wọn fún ogun láti ṣe iṣẹ fún nínú ẹgbẹ́. Wọ́n wá sí Hébrónì tí ó kún fún ìpinnu láti fi Dáfídì jẹ́ ọba lórí gbogbo Ísírẹ́lì. Gbogbo àwọn ìyókù lára àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wọ́n sì jẹ́ onínú kan láti fi Dáfídì jọba