1 Chronicles 12:40 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Bákan náà ni gbogbo àwọn aládùúgbò wọn láti ọ̀nà jíjìn bí ẹ̀yà Isakari ati ti Sebuluni ati Nafutali di oúnjẹ ru kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, ati ràkúnmí, ati ìbakasíẹ, ati akọ mààlúù wá fún wọn. Wọ́n kó ọpọlọpọ oúnjẹ, àkàrà dídùn tí wọ́n fi èso ọ̀pọ̀tọ́ ṣe, ìdì èso resini, waini, ati òróró, pẹlu akọ mààlúù ati aguntan, nítorí pé ayọ̀ kún gbogbo orílẹ̀-èdè Israẹli.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Pẹlupẹlu awọn ti o sunmọ wọn, ani titi de ọdọ Issakari, ati Sebuluni, ati Naftali, mu akara wá lori kẹtẹkẹtẹ, ati lori ibakasiẹ, ati lori ibãka, ati lori malu, ani onjẹ ti iyẹfun, eso ọ̀pọtọ, ati eso àjara gbigbẹ, ati ọti-waini, ati ororo, ati malu, ati agutan li ọ̀pọlọpọ: nitori ti ayọ̀ wà ni Israeli.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn aládùúgbò láti ọ̀nà jínjìn gẹ́gẹ́ bí Ísákárì, Ṣébúlúnì àti Náfítanì gbé oúnjẹ wá lórí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, lórí Ràkunmí, àti lórí ìbáákà àti lórí màlúù, àní oúnjẹ ti ìyẹ̀fun, èṣo àjàrà gbígbẹ, èṣo ọ̀pọ̀tọ́, àkàrà dídùn, ọtí wáìnì, òróró, màlúù àti àgùntàn, nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ayọ̀ wà ní Ísírẹ́lì.