1 Chronicles 12:8 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Àwọn ọkunrin tí wọ́n wá láti inú ẹ̀yà Gadi láti darapọ̀ mọ́ Dafidi, ní ibi ààbò tí ó wà ninu aṣálẹ̀ nìwọ̀nyí; akọni ati ògbólógbòó jagunjagun ni wọ́n, wọ́n já fáfá ninu lílo apata ati ọ̀kọ̀, ojú wọn dàbí ti kinniun, ẹsẹ̀ wọn sì yá nílẹ̀ bíi ti ẹsẹ̀ àgbọ̀nrín lórí òkè.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati ninu awọn ara Gadi, awọn ọkunrin akọni kan ya ara wọn sọdọ Dafidi ninu iho ni iju, awọn ọkunrin ogun ti o yẹ fun ija ti o le di asà on ọ̀kọ mu, oju awọn ẹniti o dabi oju kiniun, nwọn si yara bi agbọnrin lori awọn òke nla;
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Díẹ̀ lára àwọn ará Gádì yà sọ́dọ̀ Dáfídì ní ibi gíga ní ihà. Wọ́n sì jẹ́ onígboyà ológun tí ó múra fún ogun tí ó sì lágbára láti di àṣà àti ẹsin mú. Ojú wọn sì dàbí ojú kìnìún, wọ́n sì yára bí àgbọ̀nrín lórí àwọn òkè.