1 Chronicles 13:11 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Inú bí Dafidi nítorí pé Ọlọrun lu Usa pa, láti ọjọ́ náà ni a ti ń pe ibẹ̀ ní Peresi Usa títí di òní.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Dafidi si binu nitori ti Oluwa ké Ussa kuro: nitorina ni a ṣe pè ibẹ na ni Peres-Ussa titi di oni.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà Dáfídì sì bínú nítorí ìbínú OLÚWA ké jáde lórí Úsá, àti títí di òní, wọ́n sì ń pe ibẹ̀ ní péresì-Ùsà.