1 Chronicles 13:2 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Lẹ́yìn náà ó sọ fún gbogbo ìjọ Israẹli pé, “Bí ó bá dára lójú yín, tí ó sì jẹ́ ìfẹ́ OLUWA Ọlọrun wa, ẹ jẹ́ kí á ranṣẹ lọ sọ́dọ̀ àwọn eniyan wa tí wọ́n ṣẹ́kù ní ilé Israẹli, ati àwọn alufaa ati àwọn ọmọ Lefi ní àwọn ìlú tí wọ́n ní pápá oko, kí wọ́n wá darapọ̀ mọ́ wa.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Dafidi si wi fun gbogbo ijọ Israeli pe, Bi o ba dara loju nyin, bi o ba si ti ọwọ Oluwa Ọlọrun wa wá, jẹ ki a ranṣẹ kiri sọdọ awọn arakunrin wa ni ibi gbogbo, ti o kù ni gbogbo ilẹ Israeli, ati pẹlu wọn si alufa ati awọn ọmọ Lefi ti mbẹ ni ilu agbegbe wọn, ki nwọn ki o le ko ara wọn jọ sọdọ wa:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó sì wí fún gbogbo àwọn ìjọ Ísírẹ́lì pé Tí ó bá dára lójú yín àti tí ó bá ṣe jẹ́ àṣẹ OLÚWA Ọlọ́run wa, jẹ́ kí a ránṣẹ́ sí ọ̀nà jínjìn àti gbígbòòrò sí àwọn arákùnrin wa tó kù ní gbogbo àwọn agbègbè ìlú Ísírẹ́lì àti pẹ̀lú àwọn àlùfáà àti àwọn ará Léfì àwọn tí ó wà pẹ̀lú wọn nínú ìlú wọn àti pápá oko tútù, láti wá kó ara wọn jọpọ̀ sọ́dọ̀ wa.