1 Chronicles 13:5 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nítorí náà Dafidi kó àwọn ọmọ Israẹli jọ láti Ṣihori ní Ijipti títí dé ẹnubodè Hamati láti lọ gbé Àpótí Majẹmu Ọlọrun láti Kiriati Jearimu lọ sí Jerusalẹmu.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bẹ̃ni Dafidi ko gbogbo Israeli jọ lati odò Egipti ani titi de Hemati, lati mu apoti ẹri Ọlọrun lati Kirjat-jearimu wá.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà ni Dáfídì pe gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jọ, láti ọ̀dọ̀ Ṣíhórì ní Éjíbítì lọ sí Lébò ní ọ̀nà à bá wọ Hámátì, láti gbé àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run padà láti Kiriati Jéárímù.