1 Chronicles 13:6 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Dafidi ati gbogbo ọmọ Israẹli lọ sí ìlú Baala, tí à ń pè ní Kiriati Jearimu, ninu ilẹ̀ ẹ̀yà Juda, wọ́n lọ gbé Àpótí Majẹmu tí à ń fi orúkọ OLUWA pè, OLUWA tí ó jókòó, tí ó fi àwọn Kerubu ṣe ìtẹ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Dafidi si gòke ati gbogbo Israeli si Baala, si Kirjat-jearimu, ti iṣe ti Juda, lati mu apoti ẹ̀ri Ọlọrun Oluwa gòke lati ibẹ wá, ti ngbe arin Kerubimu, nibiti a npe orukọ Ọlọrun.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Dáfídì àti gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pẹ̀lú Rẹ̀ lọ sí Báláhì ti Júdà (Kiriati-Jéárímù) láti gbé àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run OLÚWA tí a fi orúkọ Rẹ̀ pè, tí ó jókòó láàrin kérúbù-gòkè wá.