1 Chronicles 14:1 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Hiramu, ọba Tire kó àwọn òṣìṣẹ́ ranṣẹ sí Dafidi, pẹlu igi kedari ati àwọn ọ̀mọ̀lé ati àwọn gbẹ́nàgbẹ́nà láti bá a kọ́ ilé rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
HIRAMU ọba Tire si ran onṣẹ si Dafidi, ati igi Kedari, pẹlu awọn ọmọle ati gbẹnagbẹna, lati kọ́le fun u.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nísinsìn yìí Hírámù àti ọba Tírè rán oníṣẹ́ sí Dáfídì, àti pẹ̀lú igi kédérì pẹ̀lú àwọn ọ̀mọ̀lé àti gbẹ́nàgbẹ́nà láti kọ́ ààfin fún un.