1 Chronicles 14:15 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nígbà tí o bá ń gbọ́ ìró ẹsẹ̀ lórí àwọn igi balisamu ni kí o kọlù wọ́n, nítorí pé n óo ṣáájú rẹ lọ láti kọlu ogun Filistini.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Yio si ṣe, nigbati iwọ ba gbọ́ iro ẹsẹ lòke igi mulberi, nigbana ni ki iwọ ki o gbogun jade: nitori Ọlọrun jade ṣaju rẹ lọ lati kọlù ogun awọn ara Filistia.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Tí ó bá sì ṣe, tí ẹ̀yin bá ti gbọ́ ìró yíyan ẹsẹ̀ ní orí òkè igi Bálísámù, ẹ jáde fún ogun, nítorí èyí yóò fi hàn pé Ọlọ́run ti jáde níwájú rẹ láti kọlu àwọn ọmọ ogun Fílístínì.