1 Chronicles 14:8 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nígbà tí àwọn ará Filistia gbọ́ pé wọ́n ti fi òróró yan Dafidi lọ́ba lórí Israẹli, gbogbo wọn wá gbógun ti Dafidi. Nígbà tí Dafidi gbọ́, òun náà múra láti lọ gbógun tì wọ́n.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati awọn ara Filistia si gbọ́ pe, a fi ororo yan Dafidi li ọba lori gbogbo Israeli, gbogbo awọn ara Filistia gòke lọ iwá Dafidi: Dafidi si gbọ́, o si jade tọ̀ wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí àwọn ará Fílístínì gbọ́ pé a ti fi àmì òróró yàn Dáfídì ní ọba lórí gbogbo Ísírẹ́lì, wọ́n sì lọ sókè pẹ̀lú ipá láti wá a rí, ṣùgbọ́n Dáfídì gbọ́ nípa Rẹ̀ ó sì jáde lọ láti pàdé wọn.