1 Chronicles 15:12 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
ó sọ fún wọn pé, “Ẹ̀yin ni olórí ìdílé yín ninu ẹ̀yà Lefi. Ẹ ya ara yín sí mímọ́, ẹ̀yin ati àwọn eniyan yín, kí ẹ baà lè gbé Àpótí Majẹmu OLUWA Ọlọrun Israẹli wá síbi tí mo ti tọ́jú sílẹ̀ fún un.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si wi fun wọn pe, Ẹnyin li olori awọn baba awọn ọmọ Lefi: ẹ ya ara nyin si mimọ́, ẹnyin ati awọn arakunrin nyin, ki ẹnyin ki o le gbé apoti ẹri Oluwa Ọlọrun Israeli gòke lọ si ibi ti mo ti pèse fun u.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó sì fí fún wọn pé, Ẹ̀yin ni olórí àwọn ìdílé Léfì; ẹ̀yin àti àwọn Léfì ènìyàn yín, ẹ ya ara yín sí mímọ́ kí ẹ lè gbé àpótí-ẹ̀rí OLÚWA, Ọlọ́run Ísírẹ́lì, lọ sí ibi tí mó ti pèsè sílẹ̀ fún un.