1 Chronicles 15:16 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Dafidi pàṣẹ fún àwọn olórí ninu àwọn ọmọ Lefi pé kí wọ́n yan àwọn akọrin láàrin ara wọn, tí wọn yóo máa fi ohun èlò orin bíi hapu, dùùrù, ati aro dá orin ayọ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Dafidi si wi fun olori awọn ọmọ Lefi pe ki nwọn yàn awọn arakunrin wọn, awọn akọrin pẹlu ohun èlo orin, psalteri ati duru, ati kimbali; ti ndún kikan ti o si nfi ayọ gbé ohùn soke.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Dáfídì sọ fún àwọn olórí àwọn Léfì láti yan àwọn arákùnrin wọn gẹ́gẹ́ bí akọrin láti kọ orin ayọ̀, pẹ̀lú àwọn ohun-èlò orin pisalitérì, dùùrù, àti Ṣíḿbálì.