1 Chronicles 15:2 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Dafidi bá dáhùn pé, “Àwọn ọmọ Lefi nìkan ni wọ́n gbọdọ̀ ru Àpótí Majẹmu OLUWA, nítorí àwọn ni Ọlọrun yàn láti máa rù ú, ati láti máa ṣiṣẹ́ ìsìn rẹ̀ títí lae.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbana ni Dafidi wipe, Ẹnikan kò yẹ lati rù apoti ẹri Ọlọrun bikoṣe awọn ọmọ Lefi; nitori awọn ni Oluwa ti yàn lati ma gbé apoti ẹri Ọlọrun, ati lati ma ṣe iranṣẹ fun u titi lai.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà Dáfídì wí pé, Kò sí ẹnìkan àyàfi àwọn ọmọ Léfì ni ó lè gbé Àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run, nítorí OLÚWA yàn wọ́n láti gbé àpóti ẹ̀rí OLÚWA àti láti máa ṣe ìránṣẹ́ níwájú Rẹ̀ títí láé.