1 Chronicles 15:24 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Àwọn alufaa tí wọ́n yàn láti máa fọn fèrè níwájú Àpótí Majẹmu Ọlọrun ni: Ṣebanaya, Joṣafati, Netaneli, Amasa, Sakaraya, Bẹnaya, ati Elieseri. Obedi Edomu ati Jehaya pẹlu ń ṣọ́ ẹnu ọ̀nà ibi tí wọ́n gbé Àpótí Majẹmu sí.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati Ṣebaniah, ati Jehoṣafati, ati Netaneeli, ati Amasai, ati Sekariah, ati Benaiah, ati Elieseri, awọn alufa, li o nfun ipè niwaju apoti ẹri Ọlọrun: ati Obed-Edomu, ati Jehiah li awọn adena fun apoti ẹri na.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣébéáníá, Jóṣáfátì, Nétanélì, Ámásáyì, Ṣekaríyà, Beniáyà àti Élíásérì ní àwọn àlùfáà, ti o ń fún ìpè níwájú àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run. Obedi-Édómù àti Jéhíyà ni ó sì gbọdọ̀ jẹ́ olùsọ́nà fún àpótí ẹ̀rí.