1 Chronicles 15:28 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Bẹ́ẹ̀ ni gbogbo Israẹli ṣe gbé Àpótí Majẹmu OLUWA pẹlu ìró orin ayọ̀, tí wọn ń fi oríṣìíríṣìí ohun èlò orin bíi ipè, fèrè, aro, hapu ati dùùrù kọ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bayi ni gbogbo Israeli gbé apoti ẹri majẹmu Oluwa gòke wá pẹlu iho ayọ̀, ati iró fère, ati pẹlu ipè, ati kimbali, psalteri ati duru si ndún kikankikan.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bẹ́ẹ̀ ni gbogbo Ísírẹ́lì gbé àpótí ẹ̀rí àti májẹ̀mú OLÚWA gòkè wá pẹ̀lú ariwo, pèlú àyíká ìhó ayọ̀ àti láti fọn fèrè ti ìpè, àti kíḿbálì, àti láti ta písálítérì; àti dùùrù olóhun goro.