1 Chronicles 15:29 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Bí wọ́n ti ń gbé Àpótí Majẹmu OLUWA wọ ìlú Dafidi, Mikali ọmọbinrin Saulu yọjú láti ojú fèrèsé, ó rí Dafidi tí ń jó, tí ń fò sókè tayọ̀tayọ̀, ó sì pẹ̀gàn rẹ̀ ninu ara rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si ṣe bi apoti ẹri majẹmu Oluwa na ti de ilu Dafidi ni Mikali ọmọ Saulu obinrin yọju wode ni fèrese, o ri Dafidi ọba njó, o si nṣire; o si kẹgan rẹ̀ li ọkàn rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bí àpótí ẹ̀rí májẹ̀mú OLÚWA ti ń wọ ìlú ńlá Dáfídì, Míkálì ọmọbìnrin Ṣọ́ọ̀lù ń wò láti ojú fèrèsé nígbà tí ó sì rí ọba Dáfídì ń jó, ó sì ń ṣe àjọyọ̀, ó sì kẹ́gàn Rẹ̀ ní ọkàn Rẹ̀.