1 Chronicles 16:35 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ẹ kígbe pé, “Gbà wá, Ọlọrun, olùgbàlà wa, kó wa jọ, sì gbà wá láàrin àwọn orílẹ̀-èdè, kí á lè máa dúpẹ́, kí á máa yin orúkọ mímọ́ rẹ, kí á sì máa ṣògo ninu ìyìn rẹ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ki ẹ si wipe, Gbà wa Ọlọrun igbala wa, si gbá wa jọ, ki o si gbà wa lọwọ awọn keferi, ki awa ki o le ma fi ọpẹ fun orukọ rẹ mimọ́, ki a si le ma ṣogo ninu iyin rẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Sunkún jáde, “Gbà wá, Ọlọ́run Olùgbàlà a wa; kówajọ kí o sì gbà wá kúrò lọ́wọ́ àwọn orílẹ̀ èdè, kí àwa kí ó lè fí ọpẹ́ fún orúkọ mímọ́ rẹ, kí àwa kí ó lè yọ̀ nínú ìyìn Rẹ̀.”