1 Chronicles 16:4 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ó sì yan àwọn ọmọ Lefi kan láti máa ṣe ètò ìsìn níwájú Àpótí Majẹmu OLUWA: láti máa gbadura, láti máa dúpẹ́, ati láti máa yin OLUWA Ọlọrun Israẹli.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si yan ninu awọn ọmọ Lefi lati ma jọsin niwaju apoti ẹri Oluwa, ati lati ṣe iranti, ati lati dupẹ, ati lati yìn Oluwa Ọlọrun Israeli:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó yan díẹ̀ lára àwọn ará Léfì láti máa jọ́sìn níwájú àpótí ẹ̀rí OLÚWA, àti láti ṣe ìrántí àti dúpẹ́ àti láti yin OLÚWA, Ọlọ́run Ísírélì.