1 Chronicles 16:41 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Hemani wà pẹlu wọn, ati Jedutuni ati àwọn mìíràn tí a yàn, tí a sì dárúkọ, láti máa dúpẹ́ lọ́wọ́ OLUWA nítorí ìfẹ́ ńlá rẹ̀ tí kì í yẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati pẹlu wọn Hemani ati Jedutuni, ati awọn iyokù ti a yàn, ti a si pe li orukọ, lati ma fi ìyin fun Oluwa, nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai;
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Pẹ̀lú wọn ni Hémánì àti Jédútúnì àti ìyókù tí a mú àti yàn nípaṣẹ̀ orúkọ láti fi ọpẹ́ fún OLÚWA Nítorí tí ìfẹ́ Rẹ̀ dúró títí láéláé