1 Chronicles 17:1 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ní ọjọ́ kan ní àkókò tí Dafidi ọba ń gbe ààfin rẹ̀, ó sọ fún Natani, wolii, pé, “Wò ó, èmi ń gbé ilé tí a fi igi kedari kọ́, ṣugbọn Àpótí Majẹmu OLUWA wà ninu àgọ́.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O SI ṣe, bi Dafidi ti joko ninu ile rẹ̀, ni Dafidi sọ fun Natani woli pe, Wò o, emi ngbe inu ile kedari, ṣugbọn apoti ẹri majẹmu Oluwa ngbe abẹ aṣọ-tita.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Lẹ́yìn ìgbà tí Dáfídì ti fi ìdí kalẹ̀ sínú ààfin Rẹ̀, ó sọ fún Nátanì wòlíì pé, Èmi nìyí, tí ń gbé inú òpèpè (igi) ààfin kédárì nígbà tí àpótí ẹ̀rí májẹ̀mú OLÚWA wà lábẹ́ àgọ́