1 Chronicles 17:11 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nígbà tí ọjọ́ bá pé tí ó bá kú, tí a sin ín pẹlu àwọn baba rẹ̀, n óo gbé ọ̀kan ninu àwọn ọmọ rẹ̀ dìde, àní ọ̀kan ninu àwọn ọmọkunrin rẹ̀, n óo sì fìdí ìjọba rẹ̀ múlẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Yio si ṣe, nigbati ọjọ rẹ ba pe, ti iwọ o lọ pẹlu awọn baba rẹ, ni emi o gbé iru-ọmọ rẹ dide lẹhin rẹ, ti yio jẹ ọkan ninu awọn ọmọ rẹ ọkunrin; emi o si fi idi ijọba rẹ̀ mulẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà ti ọjọ́ rẹ bá kọjá, tí ìwọ bá lọ láti lọ bá àwọn baba à rẹ, Èmi yóò gbé àwọn ọmọ rẹ sókè láti rọ́pò rẹ, ọ̀kan lára àwọn ọmọ tìrẹ, Èmi yóò sì fìdí ìjọba Rẹ̀ kalẹ̀.