1 Chronicles 17:21 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ní gbogbo ayé, orílẹ̀-èdè wo ni ó tún dàbí Israẹli, àwọn eniyan rẹ, tí ìwọ Ọlọrun rà pada láti jẹ́ eniyan rẹ, tí o sì sọ orúkọ rẹ̀ di ńlá nípa àwọn iṣẹ́ ìyanu tí o ṣe nígbà tí ó lé àwọn orílẹ̀-èdè kúrò níwájú àwọn eniyan rẹ, tí o rà pada láti ilẹ̀ Ijipti?
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Orilẹ-ède kan wo li o wà li aiye ti o dabi enia rẹ, Israeli, ti Ọlọrun lọ irapada lati ṣe enia on tikararẹ, lati ṣe orukọ fun ara rẹ nipa ohun ti o tobi ti o si lẹ̀ru, ni lile awọn orilẹ-ède jade kuro niwaju awọn enia rẹ, ti iwọ ti rapada lati Egipti jade wá?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Pẹ̀lú ta ni ó dà bí àwọn ènìyàn rẹ Ísírẹ́lì-orílẹ̀ èdè kan ní ayé, tí Ọlọ́run jáde lọ láti ra àwọn ènìyàn kan padà fún ara Rẹ̀, àti láti lè ṣe orúkọ fún ara à rẹ, àti lati ṣe ohun ńlá àti ọwọ́ ìyanu nípa lílé àwọn orílẹ̀ èdè kúrò níwáju àwọn ènìyàn Rẹ̀, ẹni tí ó gbà là láti Éjíbítì?