1 Chronicles 17:24 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Orúkọ rẹ yóo fìdí múlẹ̀ sí i, àwọn eniyan rẹ yóo sì máa gbé ọ́ ga títí lae, wọn yóo máa wí pé ‘OLUWA àwọn ọmọ ogun, tí ó jẹ́ Ọlọrun Israẹli ni Israẹli mọ̀ ní Ọlọrun,’ ati pé ìdílé Dafidi, iranṣẹ rẹ, yóo fìdí múlẹ̀ sí i níwájú rẹ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ani, jẹ ki o fi idi mulẹ, ki a le ma gbé orukọ rẹ ga lailai, wipe, Oluwa awọn ọmọ ogun li Ọlọrun Israeli, ani Ọlọrun fun Israeli; si jẹ ki ile Dafidi iranṣẹ rẹ ki o fi idi mulẹ niwaju rẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Kí ó lè di fifi ìdí múlẹ̀ àti kí orúkọ rẹ di gbígbéga títí láé. Nígbà náà ni àwọn ọkùnrin yóò wí pé, ‘OLÚWA, ni Ọlọ́run Isírẹ́lì.’ Ilé ìransẹ́ rẹ Dáfídì sì ni a ó fi ìdí Rẹ̀ múlẹ̀ níwáju rẹ.