1 Chronicles 17:27 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nítorí náà, jẹ́ kí ó wù ọ́ láti bukun ìdílé èmi iranṣẹ rẹ, kí ìdílé mi lè wà níwájú rẹ títí lae, nítorí ẹnikẹ́ni tí o bá bukun, olúwarẹ̀ di ẹni ibukun títí lae.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Njẹ nisisiyi jẹ ki o wù ọ lati bukún ile iranṣẹ rẹ, ki o le ma wà niwaju rẹ lailai: nitori iwọ Oluwa, ẹniti o sure fun, ire ni o si ma jẹ lailai.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nísinsìn yìí ó ti tẹ́ ọ lọ́rùn láti bùkún ilé ìransẹ́ rẹ kí ó lè tẹ̀ṣíwájú ní ojú rẹ; nitorí ìwọ, OLÚWA, ti bùkún un, a ó sì bùkun-un títí láéláé.”