1 Chronicles 17:6 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Sọ pé, mo ní ninu gbogbo ibi tí mo ti ń bá àwọn ọmọ Israẹli lọ káàkiri, ǹjẹ́ mo tíì yanu bèèrè lọ́wọ́ onídàájọ́ kankan, lára àwọn tí mo pàṣẹ fún láti máa darí àwọn eniyan mi, pé kí wọ́n kọ́ ilé kedari fún mi?’
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nibikibi ti mo ti nrin larin gbogbo Israeli, emi ha sọ̀rọ kan fun ọkan ninu awọn onidajọ Israeli, ti emi ti paṣẹ fun lati ma bọ awọn enia mi, emi ha ti wipe, Ẽṣe ti ẹnyin kò fi kọ́ ile igi kedari fun mi bi?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ni ibi gbogbo tí mo ti bá gbogbo Isírẹ́lì rìn dé, ǹjẹ́ mo wí nǹkankan sí ọ̀kan nínú àwọn adarí Ísírẹ́lì, tí èmí pàṣẹ́ fún láti máa jẹ́ olùṣọ́-àgùntàn àwọn ènìyàn mi, wí pé, “Kí ní ṣe tí ẹ̀yín kò fi kọ́ ilé tí a fi igi kédárì kọ́ fún mi?” ’