1 Chronicles 17:7 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
“Nítorí náà, sọ fún un pé, èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun ní ‘mo mú un wá láti inú pápá, níbi tí ó ti ń da ẹran, pé kí ó wá jọba lórí, àwọn eniyan mi, Israẹli.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Njẹ nitorina bayi ni iwọ o wi fun Dafidi iranṣẹ mi, Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi, Emi mu ọ kuro ni pápá oko-tutu, ani kuro lati ma tọ agutan lẹhin, ki iwọ ki o le ma ṣe olori awọn enia mi Israeli.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Nígbà náà, sọ fún ìránṣẹ́ mi Dáfídì pé, ‘Èyí ni ohun tí OLÚWA alágbára wí: Èmi mú un yín láti pápá oko tútù wá, àní kúrò lẹ́yìn agbo àgùntàn, kí ìwọ lè máa ṣe olórí àwọn ènìyàn mi Ísírẹ́lì.