1 Chronicles 17:8 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Mo sì ń wà pẹlu rẹ̀ ní gbogbo ibi tí ó ń lọ, mo sì ti pa àwọn ọ̀tá rẹ̀ run níwájú rẹ̀, n óo sì gbé orúkọ rẹ̀ ga bí orúkọ àwọn eniyan ńlá ayé.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Emi si ti wà pẹlu rẹ ni ibikibi ti iwọ ba lọ, emi si ti ké gbogbo awọn ọta rẹ kuro niwaju rẹ, emi o si ṣe ọ li olorukọ kan, bi orukọ awọn enia nla ti o ti wà li aiye.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èmi ti wà pẹ̀lú yín ní, ibi kíbi tí ẹ̀yin ti ń lọ, ẹ̀mi sì ti gé gbogbo àwọn ọ̀ta yín kúrò níwáju yín. Nísinsin yìí Èmi yóò mú kí orúkọ rẹ kí ó dàbí orukọ àwọn ènìyàn ńlá jùlọ̀ tí ó wà ní ayé.