1 Chronicles 17:9 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
N óo yan ibìkan fún Israẹli, àwọn eniyan mi, n óo fìdí wọn múlẹ̀, wọn óo máa gbé ilẹ̀ wọn, ẹnikẹ́ni kò ní yọ wọ́n lẹ́nu mọ́, àwọn ìkà kò tún ní ṣe wọ́n lófò mọ́ bíi ti àtijọ́,
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Emi o si yan ibi kan fun Israeli awọn enia mi, emi o si gbìn wọn, ki nwọn le má gbe ipò wọn, a kì yio si ṣì wọn mọ; bẹ̃ni ọmọ buburu kì yio yọ wọn lẹnu mọ, bi ti atijọ;
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èmi yóò sì pèṣè àyè kan fún àwọn ènìyàn mi Ísírẹ́lì, kí wọn kí ó lè ní ilé ti wọn kí a má sì se dàmú wọn mọ́. Àwọn ènìyàn búburú kì yóò ni wọ́n lára mọ́, gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti se ní ìbẹ̀rẹ̀.