1 Chronicles 18:10 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
ó rán Hadoramu, ọmọ rẹ̀, pé kí ó lọ kí Dafidi ọba, kí ó sì bá a yọ ayọ̀ ìṣẹ́gun tí ó ní lórí Hadadeseri, nítorí Hadadeseri ti bá Toi pàápàá jagun ní ọpọlọpọ ìgbà. Toi sì fi oríṣìíríṣìí ohun èlò wúrà, fadaka, ati idẹ ranṣẹ sí Dafidi.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O ran Hadoramu ọmọ rẹ̀ si Dafidi ọba lati ki i ati lati yọ̀ fun u, nitoriti o ti ba Hadareseri jà o si ti ṣẹgun rẹ̀; (nitori Tou ti jẹ ọta Hadareseri) o si ni oniruru ohun elo wura ati ti fadakà ati idẹ pẹ̀lu rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó rán ọmọ Rẹ̀ Ádórámì sí ọba Dáfídì láti kí i àti láti lọ bá a yọ̀ lórí ìṣẹ́gun Rẹ̀ nínú ogun lórí Hádádéṣérì, tí ó wà lójú ogun pẹ̀lú Tóù. Ádórámì mú oríṣiríṣi ohun èlò ti wúrà àti fàdákà àti tan-gan-ran wá.