1 Chronicles 18:11 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Dafidi yà wọ́n sí mímọ́ fún OLUWA, fún iṣẹ́ ìsìn pẹlu àwọn fadaka ati wúrà tí ó gbà lọ́wọ́ àwọn orílẹ̀-èdè tí ó ti ṣẹgun: àwọn bíi Edomu ati Moabu, Amoni, Filistini ati Amaleki.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn pẹlu ni Dafidi yà si mimọ́ fun Oluwa pẹlu fadakà ati wura ti o ko lati ọdọ gbogbo orilẹ-ède wọnni wá; lati Edomu, ati lati Moabu, ati lati ọdọ awọn ọmọ Ammoni, ati lati ọdọ awọn ara Filistia, ati lati Amaleki wá,
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ọba Dáfídì ya ohun èlò wọ̀n yí sí mímọ́ fún OLÚWA, gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe pẹ̀lú fàdákà àti wúrà tí ó ti mú láti gbogbo àwọn orílẹ̀ èdè wọ̀nyí: Édómù àti Móábù, ará Ámónì àti àwọn ará Fílístínì àti Ámálékì.