1 Chronicles 18:4 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Dafidi gba ẹgbẹrun (1,000) kẹ̀kẹ́ ogun, ẹẹdẹgbaarin (7,000) ọmọ ogun ẹlẹ́ṣin, ati ọ̀kẹ́ kan (20,000) ọmọ ogun lọ́wọ́ rẹ̀. Ó rọ́ àwọn ẹṣin náà lẹ́sẹ̀, ṣugbọn ó dá àwọn kan sí fún ọgọrun-un (100) kẹ̀kẹ́ ogun.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Dafidi si gbà ẹgbẹrun kẹkẹ́, ati ẹ̃dẹgbarun ẹlẹṣin, ati ẹgbãwa ẹlẹsẹ lọwọ rẹ̀: Dafidi si ja iṣan ẹsẹ gbogbo awọn ẹṣin kẹkẹ́ na, ṣugbọn o pa ọgọrun ẹṣin kẹkẹ́ mọ ninu wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Dáfídì fi agbára gba ẹgbẹ̀rún (1000) kẹ̀kẹ́ Rẹ̀, ẹgbẹ̀rún méje (7,000) a gun kẹ̀kẹ́ àti ẹgbàá méjì ológun ilẹ̀. Ó sì já gbogbo ọgọ́rùn ún iṣan ẹsẹ̀ àwọn kẹ̀kẹ́ ẹsin náà.