1 Chronicles 18:8 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ó kó ọpọlọpọ idẹ ní Tibihati ati Kuni, tí wọ́n wà lábẹ́ Hadadeseri. Idẹ yìí ni Solomoni fi ṣe agbada omi ńlá ati òpó ati àwọn ohun èlò idẹ fún ilé OLUWA.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Lati Tibhati pẹlu ati lati Kuni, ilu Hadareseri ni Dafidi ko ọ̀pọlọpọ idẹ, eyiti Solomoni fi ṣe okun idẹ, ọwọn wọnni, ati ohun elo idẹ wọnni.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Láti Tébà àti Kúnì, ìlú tí ó jẹ́ ti Hádádéṣérì, Dáfídì mú ọ̀pọ̀ tánganran tí Ṣólómónì lò láti fi ṣe òkun tan-gan-ran, àwọn òpó àti orísìí ohun èlò tan-gan-ran.